Luk 21:24-30 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nwọn o si ti oju idà ṣubu, a o si dì wọn ni igbekun lọ si orilẹ-ède gbogbo: Jerusalemu yio si di itẹmọlẹ li ẹsẹ awọn Keferi, titi akoko awọn Keferi yio fi kún.

25. Àmi yio si wà li õrùn, ati li oṣupa, ati ni irawọ; ati lori ilẹ aiye idamu fun awọn orilẹ-ede nitori ipaiya ti ariwo;

26. Aiya awọn enia yio ma já fun ibẹru, ati fun ireti nkan wọnni ti mbọ̀ sori aiye: nitori awọn agbara ọrun li a o mì titi.

27. Nigbana ni nwọn o si ri Ọmọ-enia ti yio ma ti oju ọrun bọ̀ ti on ti agbara ati ogo nla.

28. Ṣugbọn nigbati nkan wọnyi ba bẹ̀rẹ si iṣẹ, njẹ ki ẹ wò òke, ki ẹ si gbé ori nyin soke; nitori idande nyin kù si dẹ̀dẹ.

29. O si pa owe kan fun wọn pe; Ẹ kiyesi igi ọpọtọ, ati si gbogbo igi;

30. Nigbati nwọn ba rúwe, ẹnyin ri i, ẹ si mọ̀ fun ara nyin pe, igba ẹ̀run kù fẹfẹ.

Luk 21