14. Nitorina ẹ pinnu rẹ̀ li ọkàn nyin pe ẹ kì yio ronu ṣaju, bi ẹ o ti dahun.
15. Nitoriti emi ó fun nyin li ẹnu ati ọgbọ́n, ti gbogbo awọn ọtá nyin kì yio le sọrọ-òdi si, ti nwọn kì yio si le kò loju.
16. A o si fi nyin hàn lati ọdọ awọn õbi nyin wá, ati awọn arakunrin, ati awọn ibatan, ati awọn ọrẹ́ wá; nwọn o si mu ki a pa ninu nyin.
17. A o si korira nyin lọdọ gbogbo enia nitori orukọ mi.
18. Ṣugbọn irun ori nyin kan kì o ṣegbé.
19. Ninu sũru nyin li ẹnyin o jère ọkàn nyin.
20. Nigbati ẹnyin ba si ri ti a fi ogun yi Jerusalemu ká, ẹ mọ̀ nigbana pe, isọdahoro rẹ̀ kù si dẹ̀dẹ.
21. Nigbana ni ki awọn ti mbẹ ni Judea ki o sá lọ sori òke; ati awọn ti mbẹ larin rẹ̀ ki nwọn jade kuro; ki awọn ti o si mbẹ ni igberiko ki o máṣe wọ̀ inu rẹ̀ lọ.