43. Ibukun ni fun ọmọ-ọdọ na, nigbati oluwa rẹ̀ ba de, ti yio ba a ki o ma ṣe bẹ̃.
44. Lõtọ ni mo wi fun nyin, yio si fi i jẹ olori ohun gbogbo ti o ni.
45. Ṣugbọn bi ọmọ-ọdọ na ba wi li ọkàn rẹ̀ pe, Oluwa mi yẹ̀ igba atibọ̀ rẹ̀; ti o si bẹ̀rẹ si ilù awọn iranṣẹkunrin ati iranṣẹbinrin, ti o si bẹ̀rẹ si ijẹ ati si imu amupara;
46. Oluwa ọmọ-ọdọ na yio de li ọjọ ti kò reti rẹ̀, ati ni wakati ti kò daba, yio si jẹ ẹ niya gidigidi, yio si yàn ipò rẹ̀ pẹlu awọn alaigbagbọ́.
47. Ati ọmọ-ọdọ na, ti o mọ̀ ifẹ oluwa rẹ̀, ti kò si mura silẹ ti kò si ṣe gẹgẹ bi ifẹ rẹ̀, on li a o nà pipọ.
48. Ṣugbọn eyi ti kò mọ̀, ti o ṣe ohun ti o yẹ si lilu, on li a o lù niwọn. Nitori ẹnikẹni ti a fun ni pipọ, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère pipọ: lọdọ ẹniti a ba gbé fi pipọ si, lọdọ rẹ̀ li a o gbé bère si i.
49. Iná li emi wá lati fọ̀n si aiye; kili emi si nfẹ bi a ba ti da a ná?
50. Ṣugbọn emi ni baptismu kan ti a o fi baptisi mi; ara ti nni mi to titi yio fi pari!