Luk 12:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. O si ṣe, nigbati ainiye ijọ enia pejọ pọ̀, tobẹ̃ ti nwọn ntẹ̀ ara wọn mọlẹ, o tètekọ́ wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Ẹ mã ṣọra nyin nitori iwukara awọn Farisi, ti iṣe agabagebe.

2. Kò si ohun ti a bò, ti a kì yio si fihàn; tabi ti o pamọ, ti a ki yio mọ̀.

3. Nitorina ohunkohun ti ẹnyin sọ li òkunkun, ni gbangba li a o gbé gbọ́; ati ohun ti ẹnyin ba sọ si etí ni ìkọkọ, lori orule li a o gbé kede rẹ̀.

4. Emi si wi fun nyin ẹnyin ọrẹ́ mi, Ẹ máṣe bẹ̀ru awọn ti ipa ara enia kú, lẹhin eyini ti nwọn kò si li eyiti nwọn le ṣe mọ́.

Luk 12