24. Lẹhin ọjọ wọnyi ni Elisabeti aya rẹ̀ lóyun, o si fi ara rẹ̀ pamọ́ li oṣù marun, o ni,
25. Bayi li Oluwa ṣe fun mi li ọjọ ti o ṣijuwò mi, lati mu ẹ̀gan mi kuro lọdọ araiye.
26. Li oṣù kẹfa a si rán angẹli Gabrieli lati ọdọ Ọlọrun lọ si ilu kan ni Galili, ti a npè ni Nasareti,
27. Si wundia kan ti a fẹ fun ọkunrin kan, ti a npè ni Josefu, ti idile Dafidi; orukọ wundia na a si ma jẹ Maria.
28. Angẹli na si tọ̀ ọ wá, o ni, Alãfia iwọ ẹniti a kọjusi ṣe li ore, Oluwa pẹlu rẹ: alabukun-fun ni iwọ ninu awọn obinrin.