21. Ẹnikẹni ti o ní àbuku ninu irúọmọ Aaroni alufa kò gbọdọ sunmọtosi lati ru ẹbọ OLUWA ti a fi iná ṣe: on li àbuku; kò gbọdọ sunmọtosi lati rubọ àkara Ọlọrun rẹ̀.
22. On o ma jẹ àkara Ọlọrun rẹ̀, ti mimọ́ julọ ati ti mimọ́.
23. Kìki on ki yio wọ̀ inu aṣọ-ikele nì lọ, bẹ̃ni ki o máṣe sunmọ pẹpẹ, nitoriti on ní àbuku; ki on ki o máṣe bà ibi mimọ́ mi jẹ́: nitori Emi li OLUWA ti o yà wọn simimọ́.
24. Mose si wi fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli.