1. OLUWA si sọ fun Mose pe,
2. Sọ fun Aaroni, ati fun awọn ọmọ rẹ̀, ati fun gbogbo awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe; Eyi li ohun ti OLUWA ti palaṣẹ, wipe,
3. Ẹnikẹni ti iṣe enia ile Israeli, ti o ba pa akọmalu tabi ọdọ-agutan, tabi ewurẹ, ninu ibudó, tabi ti o pa a lẹhin ibudó,
4. Ti kò si mú u wá si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, lati ru u li ẹbọ wi OLUWA niwaju agọ́ OLUWA: a o kà ẹ̀jẹ si ọkunrin na lọrùn, o ta ẹ̀jẹ silẹ; ọkunrin na li a o si ke kuro ninu awọn enia rẹ̀:
5. Nitori idí eyi pe, ki awọn ọmọ Israeli ki o le ma mú ẹbọ wọn wá, ti nwọn ru ni oko gbangba, ani ki nwọn ki o le mú u tọ̀ OLUWA wá, si ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, sọdọ alufa, ki o si ru wọn li ẹbọ alafia si OLUWA.
6. Ki alufa ki o si bù ẹ̀jẹ na wọ́n ori pẹpẹ OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ́ ajọ, ki o si sun ọrá na fun õrùn didún si OLUWA.