27. Ki alufa ki o si wò o ni ijọ́ keje: bi o ba si ràn siwaju li awọ ara rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li alaimọ́; àrun ẹ̀tẹ ni.
28. Bi àmi didán na ba si duro ni ipò rẹ̀, ti kò si ràn si i li awọ ara, ṣugbọn ti o dabi ẹni sújú: iwú ijóni ni, ki alufa ki o si pè e ni mimọ́: nitoripe ijóni tita ni.
29. Bi ọkunrin tabi obinrin kan ba ní àrun li ori rẹ̀ tabi li àgbọn,
30. Nigbana ni ki alufa ki o wò àrun na: si kiyesi i, bi o ba jìn jù awọ ara lọ li oju, bi irun tinrin pupa ba mbẹ ninu rẹ̀, nigbana ni ki alufa ki o pè e li aimọ́: ipẹ́ gbigbẹ ni, ani ẹ̀tẹ li ori tabi li àgbọn ni.