Joh 8:19-25 Yorùbá Bibeli (YCE)

19. Nitorina nwọn wi fun u pe, Nibo ni Baba rẹ wà? Jesu dahùn pe, Ẹnyin kò mọ̀ mi, bẹli ẹ kò mọ̀ Baba mi: ibaṣepe ẹnyin mọ̀ mi, ẹnyin iba si ti mọ̀ Baba mi pẹlu.

20. Ọ̀rọ wọnyi ni Jesu sọ nibi iṣura, bi o ti nkọ́ni ni tẹmpili: ẹnikẹni ko si mu u; nitori wakati rẹ̀ ko ti ide.

21. Nitorina o tun wi fun wọn pe, Emi nlọ, ẹnyin yio si wá mi, ẹ ó si kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: ibiti emi gbe nlọ, ẹnyin kì ó le wá.

22. Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá.

23. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin ti isalẹ wá; emi ti oke wá: ẹnyin jẹ ti aiye yi; emi kì iṣe ti aiye yi.

24. Nitorina ni mo ṣe wi fun nyin pe, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin: nitori bikoṣepé ẹ ba gbagbọ́ pe, emi ni, ẹ ó kú ninu ẹ̀ṣẹ nyin.

25. Nitorina nwọn wi fun u pe, Tani iwọ iṣe? Jesu si wi fun wọn pe, Ani eyinì ti mo ti wi fun nyin li àtetekọṣe.

Joh 8