7. Abirùn na da a lohùn wipe, Ọgbẹni, emi kò li ẹni, ti iba gbé mi sinu adagun, nigbati a ba nrú omi na: bi emi ba ti mbọ̀ wá, ẹlomiran a sọkalẹ sinu rẹ̀ ṣiwaju mi.
8. Jesu wi fun u pe, Dide, gbé akete rẹ, ki o si mã rin.
9. Lọgan a si mu ọkunrin na larada, o si gbé akete rẹ̀, o si nrìn. Ọjọ na si jẹ ọjọ isimi.
10. Nitorina awọn Ju wi fun ọkunrin na ti a mu larada pe, Ọjọ isimi li oni: kò tọ́ fun ọ lati gbé akete rẹ.
11. O si da wọn lohùn wipe, Ẹniti o mu mi larada, on li o wi fun mi pe, Gbé akete rẹ, ki o si mã rìn.
12. Nigbana ni nwọn bi i lẽre wipe, ọkunrin wo li ẹniti o wi fun ọ pe, Gbé akete rẹ, ki o si ma rìn?
13. Ẹniti a mu larada na kò si mọ̀ ẹniti iṣe: nitori Jesu ti kuto nibẹ̀, nitori awọn enia pipọ wà nibẹ̀.
14. Lẹhinna Jesu ri i ni tẹmpili o si wi fun u pe, Wo o, a mu ọ larada: máṣe dẹṣẹ mọ́, ki ohun ti o buru jù yi lọ ki o má bà ba ọ.
15. Ọkunrin na lọ, o si sọ fun awọn Ju pe, Jesu li ẹniti o mu on larada.
16. Nitori eyi li awọn Ju si nṣe inunibini si Jesu, nwọn si nwá ọ̀na ati pa a, nitoriti a nṣe nkan wọnyi li ọjọ isimi.
17. Ṣugbọn Jesu da wọn lohùn wipe, Baba mi nṣiṣẹ titi di isisiyi, emi si nṣiṣẹ.