Joh 5:42-47 Yorùbá Bibeli (YCE)

42. Ṣugbọn emi mọ̀ nyin pe, ẹnyin tikaranyin kò ni ifẹ Ọlọrun ninu nyin.

43. Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà.

44. Ẹnyin o ti ṣe le gbagbọ́, ẹnyin ti ngbà ogo lọdọ ara nyin, ti kò wá ogo ti o ti ọdọ Ọlọrun nikan wá?

45. Ẹ máṣe rò pe, emi ó fi nyin sùn lọdọ Baba: ẹniti nfi nyin sùn wà, ani Mose, ẹniti ẹnyin gbẹkẹle.

46. Nitoripe ẹnyin iba gbà Mose gbọ́, ẹnyin iba gbà mi gbọ́: nitori o kọ iwe nipa ti emi.

47. Ṣugbọn bi ẹnyin kò ba gbà iwe rẹ̀ gbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbà ọ̀rọ mi gbọ́?

Joh 5