1. NITORINA nigbati Oluwa ti mọ̀ bi awọn Farisi ti gbọ́ pe, Jesu nṣe o si mbaptisi awọn ọmọ-ẹhin pupọ jù Johanu lọ,
2. (Ṣugbọn Jesu tikararẹ̀ kò baptisi bikoṣe awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀,)
3. O fi Judea silẹ, o si tún lọ si Galili.
4. On kò si le ṣaima kọja lãrin Samaria.
5. Nigbana li o de ilu Samaria kan, ti a npè ni Sikari, ti o sunmọ eti ilẹ biri nì, ti Jakọbu ti fifun Josefu, ọmọ rẹ̀.
6. Kanga Jakọbu si wà nibẹ̀. Nitorina bi o ti rẹ̀ Jesu tan nitori ìrin rẹ̀, bẹ̀li o joko leti kanga: o si jẹ ìwọn wakati kẹfa ọjọ.