Joh 3:6-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Eyiti a bí nipa ti ara, ara ni; eyiti a si bí nipa ti Ẹmí, ẹmí ni.

7. Ki ẹnu ki o máṣe yà ọ, nitori mo wi fun ọ pe, A kò le ṣe alaitún nyin bí.

8. Afẹfẹ nfẹ si ibi ti o gbé wù u, iwọ si ngbọ́ iró rẹ̀, ṣugbọn iwọ kò mọ̀ ibi ti o ti wá, ati ibi ti o gbé nlọ: gẹgẹ bẹ̃ni olukuluku ẹniti a bí nipa ti Ẹmí.

9. Nikodemu dahùn, o si wi fun u pe, Nkan wọnyi yio ti ṣe le ri bẹ̃?

10. Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi?

11. Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Awa nsọ eyiti awa mọ̀, a si njẹri eyiti awa ti ri; ẹnyin kò si gbà ẹri wa.

12. Bi mo ba sọ̀ ohun ti aiye yi fun nyin, ti ẹnyin kò si gbagbọ́, ẹnyin o ti ṣe gbagbọ́ bi mo ba sọ ohun ti ọrun fun nyin?

13. Ko si si ẹniti o gòke re ọrun, bikoṣe ẹniti o ti ọrun sọkalẹ wá, ani Ọmọ-enia ti mbẹ li ọrun.

14. Bi Mose si ti gbé ejò soke li aginjù, gẹgẹ bẹ̃li a kò le ṣe alaigbé Ọmọ-enia soke pẹlu:

Joh 3