Joh 3:24-32 Yorùbá Bibeli (YCE)

24. Nitoriti a kò ti isọ Johanu sinu tubu.

25. Nigbana ni iyàn kan wà larin awọn ọmọ-ẹhin Johanu, pẹlu Ju kan niti ìwẹnu.

26. Nwọn si tọ̀ Johanu wá, nwọn si wi fun u pe, Rabbi, ẹniti o ti wà pẹlu rẹ loke odò Jordani, ti iwọ ti jẹrí rẹ̀, wo o, on mbaptisi, gbogbo enia si ntọ̀ ọ̀ wá.

27. Johanu dahùn o si wipe, Enia ko le ri nkankan gbà, bikoṣepe a ba ti fifun u lati ọrun wá.

28. Ẹnyin tikaranyin jẹri mi, pe mo wipe, Emi kì iṣe Kristi na, ṣugbọn pe a rán mi ṣiwaju rẹ̀.

29. Ẹniti o ba ni iyawo ni ọkọ iyawo; ṣugbọn ọrẹ́ ọkọ iyawo ti o duro ti o si ngbohùn rẹ̀, o nyọ̀ gidigidi nitori ohùn ọkọ iyawo; nitorina ayọ̀ mi yi di kíkun.

30. On kò le ṣaima pọsi i, ṣugbọn emi kò le ṣaima rẹ̀hin.

31. Ẹniti o ti oke wá ju gbogbo enia lọ: ẹniti o ti aiye wá ti aiye ni, a si ma sọ̀ ohun ti aiye: ẹniti o ti ọrun wá ju gbogbo enia lọ.

32. Ohun ti o ti ri ti o si ti gbọ́ eyina si li on njẹri rẹ̀; ko si si ẹniti o gbà ẹrí rẹ̀.

Joh 3