11. Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.
12. Lẹhin eyi, o sọkalẹ lọ si Kapernamu, on ati iya rẹ̀ ati awọn arakunrin rẹ̀, ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀: nwọn kò si gbé ibẹ̀ li ọjọ pupọ.
13. Ajọ irekọja awọn Ju si sunmọ etile, Jesu si goke lọ si Jerusalemu,
14. O si ri awọn ti ntà malu, ati agutan, ati àdaba ni tẹmpili, ati awọn onipaṣipàrọ owo joko:
15. O si fi okùn tẹrẹ ṣe paṣan, o si lé gbogbo wọn jade kuro ninu tẹmpili, ati agutan ati malu; o si dà owo awọn onipaṣipàrọ owo nù, o si bì tabili wọn ṣubu.