Joh 16:28-31 Yorùbá Bibeli (YCE)

28. Mo ti ọdọ Baba jade wá, mo si wá si aiye: ẹ̀wẹ, mo fi aiye silẹ, mo si nlọ sọdọ Baba.

29. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ wi fun u pe, Wo o, nigbayi ni iwọ nsọ̀rọ̀ gbangba, iwọ kò si sọ ohunkohun li owe.

30. Nigbayi li awa mọ̀ pe, iwọ mọ̀ ohun gbogbo, iwọ kò ni ki a bi ọ lẽre: nipa eyi li awa gbagbọ́ pe, lọdọ Ọlọrun ni iwọ ti jade wá.

31. Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin gbagbọ́ wayi?

Joh 16