21. Nigbati Jesu ti wi nkan wọnyi tan, ọkàn rẹ̀ daru ninu rẹ̀, o si jẹri, o si wipe, Lõtọ lõtọ ni mo wi fun nyin pe, ọkan ninu nyin yio fi mi hàn.
22. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ nwò ara wọn loju, nwọn nṣiye-meji ti ẹniti o wi.
23. Njẹ ẹnikan rọ̀gún si àiya Jesu, ọkan ninu awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀, ẹniti Jesu fẹràn.
24. Nitorina ni Simoni Peteru ṣapẹrẹ si i, o si wi fun u pe, Wi fun wa ti ẹniti o nsọ.
25. Ẹniti o nrọ̀gún li àiya Jesu wi fun u pe, Oluwa, tani iṣe?
26. Nitorina Jesu dahùn pe, On na ni, ẹniti mo ba fi òkele fun nigbati mo ba fi run. Nigbati o si fi i run tan, o fifun Judasi Iskariotu ọmọ Simoni.
27. Lẹhin òkele na ni Satani wọ̀ inu rẹ̀ lọ. Nitorina Jesu wi fun u pe, Ohun ti iwọ nṣe nì, yara ṣe e kánkan.
28. Kò si si ẹnikan nibi tabili ti o mọ̀ idi ohun ti o ṣe sọ eyi fun u.
29. Nitori awọn miran ninu wọn rò pe, nitori Judasi li o ni àpo, ni Jesu fi wi fun u pe, Rà nkan wọnni ti a kò le ṣe alaini fun ajọ na; tabi ki o le fi nkan fun awọn talakà.
30. Nigbati o si ti gbà òkele na tan, o jade lojukanna: oru si ni.
31. Nitorina nigbati o jade lọ tan, Jesu wipe, Nisisiyi li a yìn Ọmọ-enia logo, a si yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀.
32. Bi a ba yìn Ọlọrun logo ninu rẹ̀, Ọlọrun yio si yìn i logo ninu on tikararẹ̀, yio si yìn i logo nisisiyi.
33. Ẹnyin ọmọde, nigba diẹ si i li emi wà pẹlu nyin. Ẹnyin ó wá mi: ati gẹgẹ bi mo ti wi fun awọn Ju pe, Nibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì o le wá; bẹ̃ni mo si wi fun nyin nisisiyi.
34. Ofin titun kan ni mo fifun nyin, Ki ẹnyin ki o fẹ ọmọnikeji nyin; gẹgẹ bi emi ti fẹran nyin, ki ẹnyin ki o si le fẹran ọmọnikeji nyin.
35. Nipa eyi ni gbogbo enia yio fi mọ̀ pe, ọmọ-ẹhin mi li ẹnyin iṣe, nigbati ẹnyin ba ni ifẹ si ọmọnikeji nyin.
36. Simoni Peteru wi fun u pe, Oluwa, nibo ni iwọ nlọ? Jesu da a lohùn pe, Nibiti emi nlọ, iwọ ki ó le tọ̀ mi nisisiyi; ṣugbọn iwọ yio tọ̀ mi nikẹhin.
37. Peteru wi fun u pe, Oluwa, ẽṣe ti emi ko fi le tọ̀ ọ nisisiyi? emi o fi ẹmí mi lelẹ nitori rẹ.
38. Jesu da a lohùn wipe, Iwọ o ha fi ẹmí rẹ lelẹ nitori mi? Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Akukọ kì yio kọ, ki iwọ ki o to sẹ́ mi nigba mẹta.