Job 7:5-12 Yorùbá Bibeli (YCE)

5. Kòkoro ati ogulùtu erupẹ li a fi wọ̀ mi li aṣọ, àwọ mi bù, o si di sisun ni.

6. Ọjọ mi yara jù ọkọ̀ iwunṣọ lọ, o si di lilò li ainireti.

7. A! ranti pe afẹfẹ li ẹmi mi; oju mi kì yio pada ri rere mọ.

8. Oju ẹniti o ri mi, kì yio ri mi mọ; oju rẹ tẹ mọra mi, emi kò sí mọ́!

9. Bi awọ-sanma ti iparun, ti isi fò lọ, bẹ̃li ẹniti nlọ si ipò-okú, ti kì yio pada wá mọ.

10. Kì yio pada sinu ile rẹ̀ mọ, bẹ̃ni ipò rẹ̀ kì yio mọ̀ ọ mọ.

11. Nitorina emi kì yio pa ẹnu mi mọ, emi o ma sọ ninu irora ọkàn mi, emi o ma ṣe irahùn ninu kikoro ọkàn mi.

12. Emi ama iṣe ejo okun tabi erinmi, ti iwọ fi yàn oluṣọ tì mi?

Job 7