Job 7:1-3 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. NJẸ ija kan kò ha si fun enia lori ilẹ, ọjọ rẹ̀ pẹlu kò dabi ọjọ alagbaṣe?

2. Bi ọmọ-ọdọ ti ima kanju bojuwo ojiji, ati bi alagbaṣe ti ima kanju wọ̀na owo iṣẹ rẹ̀.

3. Bẹ̃li a mu mi ni oṣoṣu asan, oru idanilagãra ni a si là silẹ fun mi.

Job 7