Job 42:13-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

13. O si ni ọmọkunrin meje ati ọmọbinrin mẹta.

14. O si sọ orukọ akọbi ni Jemima, ati orukọ ekeji ni Kesia, ati orukọ ẹkẹta ni Keren-happuki.

15. Ati ni gbogbo ilẹ na, a kò ri obinrin ti o li ẹwa bi ọmọbinrin Jobu; baba wọn si pinlẹ fun wọn ninu awọn arakunrin wọn.

Job 42