Job 40:6-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

6. Nigbana ni OLUWA da Jobu lohùn lati inu ìji ajayika wá o si wipe:

7. Di àmure giri li ẹgbẹ rẹ bi ọkunrin, emi o bi ọ lere, ki iwọ ki o si kọ́ mi li ẹkọ́.

8. Iwọ ha fẹ imu idajọ mi di asan? iwọ o si da mi lẹbi, ki iwọ ki o le iṣe olododo?

Job 40