Job 4:9-14 Yorùbá Bibeli (YCE)

9. Nipa ifẹsi Ọlọrun nwọn a ṣegbe, nipa ẽmi ibinu rẹ̀ nwọn a parun.

10. Bibu ramuramu kiniun ati ohùn onroró kiniun ati ehin awọn ẹ̀gbọrọ kiniun li a ka.

11. Ogbo kiniun kígbe, nitori airi ohun-ọdẹ, awọn ẹ̀gbọrọ kiniun sisanra li a tukakiri.

12. Njẹ nisisiyi a fi ohun lilumọ́ kan hàn fun mi, eti mi si gbà diẹ ninu rẹ̀.

13. Ni iro inu loju iran oru, nigbati orun ìjika kun enia.

14. Ẹ̀ru bà mi ati iwarirì ti o mu gbogbo egungun mi wá pepé.

Job 4