Job 4:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Kiyesi i, on kò gbẹkẹle awọn iranṣẹ rẹ̀, ninu awọn angeli rẹ̀ ni o si ri ẹ̀ṣẹ.

19. Ambọtori awọn ti ngbe inu ile amọ̀, ẹniti ipilẹ wọn jasi erupẹ ti yio di rirun kòkoro.

20. A npa wọn run lati òwurọ di alẹ́, nwọn gbe lailai lairi ẹni kà a si.

21. A kò ha ke okùn iye wọn kuro bi? nwọn ku, ani lailọgbọn.

Job 4