4. Awọn ọmọ wọn ri daradara, nwọn dagba ninu ọ̀dan, nwọn jade lọ, nwọn kò si tun pada wá mọ́ sọdọ wọn.
5. Tali o jọ̃ kẹtẹkẹtẹ-oko lọwọ, tabi tali o tú ide kẹtẹkẹtẹ igbẹ́?
6. Eyi ti mo fi aginju ṣe ile fun, ati ilẹ iyọ̀ ni ibugbe rẹ̀.
7. O rẹrin si ariwo ilu, bẹ̃ni on kò si gbọ́ igbe darandaran.
8. Ori àtòle oke-nla ni ibujẹ oko rẹ̀, on a si ma wá ewe tutu gbogbo ri.