32. Iwọ le imu awọn ami mejejila irawọ [Massaroti] jade wá ni igba akoko wọn? tabi iwọ le iṣe àmọna Arketuru pẹlu awọn ọmọ rẹ̀?
33. Iwọ mọ̀ ilana-ilana ọrun, iwọ le ifi ijọba rẹ̀ lelẹ li aiye?
34. Iwọ le igbé ohùn rẹ soke de awọsanma, ki ọ̀pọlọpọ omi ki o le bò ọ?
35. Iwọ le iran mànamána ki nwọn ki o le ilọ, ki nwọn ki o si wi fun ọ pe, Awa nĩ!
36. Tali o fi ọgbọ́n si odo-inu, tabi tali o fi oye sinu aiya?
37. Tali o fi ọgbọ́n ka iye awọsanma, tali o si mu igo ọrun dàjade.
38. Nigbati erupẹ di lile, ati ogulutu dipọ̀?
39. Iwọ o ha dẹ ọdẹ fun abo kiniun bi, iwọ o si tẹ́ ebi ẹgbọrọ kiniun lọrun?