32. Eyi ti emi kò ri, iwọ fi kọ́ mi, bi mo ba si dẹṣẹ, emi kì yio ṣe bẹ̃ mọ́.
33. Iṣe bi ti inu rẹ pe, on o san ẹ̀san pada? njẹ on yio san a pada, iwọ iba kọ̀ ọ tabi iwọ iba fẹ ẹ, kì iṣe emi, pẹlupẹlu kili iwọ mọ̀, sọ ọ!
34. Awọn enia amoye yio wi fun mi, ati pẹlupẹlu ẹnikẹni ti nṣe ọlọgbọ́n, ti o si gbọ́ mi.
35. Jobu ti fi aimọ̀ sọ̀rọ, ọ̀rọ rẹ̀ si ṣe alaigbọ́n.
36. Ifẹ mi ni ki a dán Jobu wò de opin, nitori idahùn rẹ̀ nipa ọ̀na enia buburu;
37. Nitoripe o fi iṣọtẹ kún ẹ̀ṣẹ rẹ̀, o papẹ́ li awujọ wa, o si sọ ọ̀rọ pupọ si Ọlọrun.