Job 34:1-4 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. PẸLUPẸLU Elihu dahùn o si wipe,

2. Ẹnyin ọlọgbọ́n, ẹ gbọ́ ọ̀rọ mi, ki ẹ si dẹtisilẹ si mi, ẹnyin ti ẹ ni ìmoye.

3. Nitoripe eti a ma dán ọ̀rọ wò, bi adùn ẹnu ti itọ onjẹ wò.

4. Ẹ jẹ ki a ṣà idajọ yàn fun ara wa; ẹ jẹ ki a mọ̀ ohun ti o dara larin wa.

Job 34