Job 32:2-6 Yorùbá Bibeli (YCE)

2. Nigbana ni inu bi Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, lati ibatan idile Ramu; o binu si Jobu, nitoriti o da ara rẹ̀ lare kàka ki o da Ọlọrun lare.

3. Inu rẹ̀ si bi si awọn ọ̀rẹ rẹ̀ mẹtẹta, nitoriti nwọn kò ni idahùn, bẹ̃ni nwọn dá Jobu lẹbi.

4. Njẹ Elihu ti duro titi Jobu fi sọ̀rọ tan, nitoriti awọn wọnyi dàgba jù on lọ ni iye ọjọ.

5. Nigbati Elihu ri pe idahùn ọ̀rọ kò si li ẹnu awọn ọkunrin mẹtẹta wọnyi, nigbana ni o binu.

6. Elihu, ọmọ Barakeli, ara Busi, dahùn o si wipe, Ọmọde li emi, àgba si li ẹnyin; njẹ nitorina ni mo duro, mo si mbẹ̀ru lati fi ìmọ mi hàn nyin.

Job 32