Job 31:8-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

8. Njẹ ki emi ki o gbìn ki ẹlomiran ki o si mu u jẹ, ani ki a fà iru-ọmọ mi tu.

9. Bi aiya mi ba di fifa sipasẹ obinrin kan, tabi bi mo ba lọ ibadeni li ẹnu-ọ̀na ile aladugbo mi,

10. Njẹ ki aya mi ki o lọ ọlọ fun ẹlomiran, ki awọn ẹlomiran ki o tẹ̀ ara wọn li ara rẹ̀.

11. Nitoripe ẹ̀ṣẹ buburu li eyi; ani ẹ̀ṣẹ ìṣẹniṣẹ ni lọdọ awọn onidajọ.

12. Nitoripe iná ni eyi ti o jo de iparun, ti iba si fà gbongbo ohun ibisi mi gbogbo tu.

13. Bi mo ba si ṣe aikà ọ̀ran iranṣẹkunrin mi tabi iranṣẹbinrin mi si, nigbati nwọn ba mba mi jà;

14. Kili emi o ha ṣe nigbati Ọlọrun ba dide; nigbati o ba si ṣe ibẹwo, ohùn kili emi o dá?

15. Ẹniti o dá mi ni inu kọ li o da a? ẹnikanna ki o mọ wa ni inu?

Job 31