20. Ogo mi gberu lọdọ mi, ọrun mi si pada di titun li ọwọ mi.
21. Emi li enia ndẹti silẹ si, nwọn a si duro, nwọn a si dakẹ ninu ìgbimọ mi.
22. Lẹhin ọ̀rọ mi nwọn kò si tun sọ mọ́, ọ̀rọ mi bọ́ si wọn li eti.
23. Nwọn a si duro dè mi bi ẹnipe fun ojo; nwọn si yanu wọn gboro bi ẹnipe fun ojo àrọ-kuro.
24. Emi si rẹrin si wọn nigbati nwọn kò ba gba a gbọ́; imọlẹ oju mi ni nwọn kò le imu rẹ̀wẹsi.