1. PẸLUPẸLU Jobu si tun gbẹnu le ọ̀rọ rẹ̀ o si wipe,
2. A! ibaṣepe emi wà bi igba oṣu ti o kọja, bi ọjọ ti Ọlọrun pa mi mọ́!
3. Nigbati fitila rẹ̀ tàn si mi li ori, ati nipa imọlẹ rẹ̀ emi rìn ninu òkunkun ja.
4. Bi mo ti ri nigba ọ̀dọ́ mi, nigbati aṣiri Ọlọrun wà ninu agọ mi.
5. Nigbati Olodumare wà sibẹ pẹlu mi, nigbati awọn ọmọ mi wà yi mi ka.