4. Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá?
5. Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.
6. Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.
7. On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.
8. O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.