Job 26:3-8 Yorùbá Bibeli (YCE)

3. Bawo ni iwọ nṣe ìgbimọ ẹniti kò li ọgbọ́n, tabi bawo ni iwọ nsọdi ọ̀ran li ọ̀pọlọpọ bi o ti ri?

4. Tani iwọ mbà sọ̀rọ, ati ẹmi tani o ti ọdọ rẹ wá?

5. Awọn alailagbara ti isa-okú wáriri; labẹ omi pẹlu awọn ti ngbe inu rẹ̀.

6. Ihoho ni ipo-okú niwaju rẹ̀, ibi iparun kò si ni iboju.

7. On ni o nà ìha ariwa ọrun ni ibi ofurufu, o si fi aiye rọ̀ li oju ofo.

8. O di omiyomi pọ̀ ninu awọsanma rẹ̀ ti o nipọn; awọsanma kò si ya nisalẹ wọn.

Job 26