Job 26:10-13 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. O fi ìde yi omi-okun ka, titi de ala imọlẹ ati òkunkun.

11. Ọwọn òpo ọrun wáriri, ẹnu si yà wọn si ibawi rẹ̀.

12. O fi ipa rẹ̀ damu omi-okun, nipa oye rẹ̀ o lu agberaga jalẹjalẹ.

13. Nipa ẹmi rẹ li o ti ṣe ọrun li ọ̀ṣọ, ọwọ rẹ̀ li o ti da ejo-wiwọ́ nì.

Job 26