Job 24:11-15 Yorùbá Bibeli (YCE)

11. Awọn ẹniti nfún ororo ninu agbala wọn, ti nwọn si ntẹ ifunti àjara, ongbẹ si ngbẹ wọn.

12. Awọn enia nkerora lati ilu wá, ọkàn awọn ẹniti o gbọgbẹ kigbe soke; sibẹ Ọlọrun kò kiyesi iwère na.

13. Awọn li o wà ninu awọn ti o kọ̀ imọlẹ, nwọn kò mọ̀ ipa ọ̀na rẹ̀, bẹni nwọn kò duro nipa ọ̀na rẹ̀.

14. Panipani a dide li afẹmọ́jumọ pa talaka ati alaini, ati li oru a di olè.

15. Oju àlagbere pẹlu duro de ofefe ọjọ, o ni, Oju ẹnikan kì yio ri mi, o si fi iboju boju rẹ̀.

Job 24