14. Nitõtọ ohun ti ati yàn silẹ fun mi ni nṣe, ọ̀pọlọpọ iru bẹ li o wà li ọwọ rẹ̀.
15. Nitorina ni ara ko ṣe rọ̀ mi niwaju rẹ̀, nigbati mo ba rò o, ẹ̀ru a ba mi.
16. Nitoripe Ọlọrun ti pá mi li aiya, Olodumare si ndamu mi.
17. Nitoriti a kò ti ke mi kuro niwaju òkunkun, bẹ̃ni kò pa òkùnkùn-biribiri mọ kuro niwaju mi.