1. SUGBỌN Jobu dahùn, o si wipe,
2. Ẹ tẹti silẹ dẹdẹ si ohùn mi, ki eyi ki o jasi itunu nyin.
3. Ẹ jọwọ mi ki emi sọ̀rọ, lẹhin igbati mo ba sọ tan, iwọ ma fi ṣẹsin nṣo.
4. Bi o ṣe ti emi ni, aroye mi iṣe si enia bi, tabi ẽtiṣe ti ọkàn mi kì yio fi ṣe aibalẹ?
5. Ẹ wò mi fin, ki ẹnu ki o si yà nyin, ki ẹ si fi ọwọ le ẹnu nyin.