Job 20:10-19 Yorùbá Bibeli (YCE)

10. Awọn ọmọ rẹ̀ yio ma wá ati ri oju-rere lọdọ talaka, ọwọ rẹ̀ yio si kó ẹrù wọn pada.

11. Egungun rẹ̀ kún fun agbara igba ewe rẹ̀, ti yio ba a dubulẹ ninu erupẹ.

12. Bi ìwa buburu tilẹ dùn li ẹnu rẹ̀, bi o tilẹ pa a mọ́ nisalẹ ahọn rẹ̀.

13. Bi o tilẹ dá a si, ti kò si kọ̀ ọ silẹ, ti o pa a mọ sibẹ li ẹnu rẹ̀,

14. Ṣugbọn onjẹ rẹ̀ ninu ikùn rẹ̀ ti yipada, o jasi orõro pamọlẹ ninu rẹ̀;

15. O ti gbe ọrọ̀ mì, yio si tun bì i jade, Ọlọrun yio pọ̀ ọ yọ jade lati inu rẹ̀ wá.

16. O ti fà oró pamọlẹ mu, ahọn gunte ni yio pa a.

17. Kì yio ri odò wọnni, iṣan omi, odò ṣiṣàn oyin ati ti ori amọ́.

18. Ohun ti o ṣíṣẹ fun ni yio mu u pada, kì yio si gbe e mì; gẹgẹ bi ọrọ̀ ti o ni, kì yio si yọ̀ ninu rẹ̀.

19. Nitoriti o ninilara, o si ti kẹhinda talaka, nitoriti o fi agbara gbe ile ti on kò kọ́.

Job 20