19. Gbogbo awọn ọrẹ idimọpọ mi korira mi, awọn olufẹ mi si kẹ̀hinda mi.
20. Egungun mi lẹ mọ́ awọ ara mi ati mọ́ ẹran ara mi, mo si bọ́ pẹlu awọ ehin mi.
21. Ẹ ṣãnu fun mi, ẹ ṣãnu fun mi, ẹnyin ọrẹ mi, nitori ọwọ Ọlọrun ti bà mi.
22. Nitori kili ẹnyin ṣe lepa mi bi Ọlọrun, ti ẹran ara mi kò tẹ́ nyin lọrùn!
23. A! Ibaṣepe a le kọwe ọ̀rọ mi nisisiyi, ibaṣepe a le dà a sinu iwe!
24. Ki a fi kalamu irin ati ti ojé kọ́ wọn sinu apata fun lailai.