Job 15:21-29 Yorùbá Bibeli (YCE)

21. Iró ìbẹru mbẹ li eti rẹ̀, ninu irora ni alaparun a dide si i.

22. O kò gbagbọ pe on o jade kuro ninu okunkun; a si ṣa a sapakan fun idà.

23. O nwò kakiri fun onjẹ, wipe, nibo li o wà, o mọ̀ pe ọjọ òkunkun sunmọ tosi.

24. Ipọnju pẹlu irora ọkàn yio mu u bẹ̀ru, nwọn o si ṣẹgun rẹ̀ bi ọba ti imura ogun.

25. Nitoripe o ti nawọ rẹ̀ jade lodi si Ọlọrun, o si mura rẹ̀ le lodi si Olodumare.

26. O sure, o si fi ẹhin giga kọlu u, ani fi ike-koko apata rẹ̀ ti o nipọn.

27. Nitoriti on fi ọra rẹ̀ bo ara rẹ̀ loju, o si ṣe jabajába ọra si ẹgbẹ rẹ̀.

28. On si gbe inu ahoro ilu itakété, ati ninu ileyile ti enia kò gbe mọ́, ti o mura tan lati di àlapa.

29. On kò le ilà, bẹ̃ni ohun ini rẹ̀ kò le iduro pẹ, bẹ̃ni kò le imu pipé rẹ̀ duro pẹ lori aiye.

Job 15