12. Iranti nyin dabi ẽru, ilu-odi nyin dabi ilu-odi amọ̀.
13. Ẹ pa ẹnu nyin mọ kuro lara mi, ki emi ki o le sọ̀rọ, ohun ti mbọ̀ wá iba mi, ki o ma bọ̀.
14. Njẹ nitori kili emi ṣe nfi ehin mi bù ẹran ara mi jẹ, ti mo si gbe ẹmi mi le ara mi lọwọ?
15. Bi o tilẹ pa mi, sibẹ emi o ma gbẹkẹle e, ṣugbọn emi o ma tẹnumọ ọ̀na mi niwaju rẹ̀.
16. Eyi ni yio si ṣe igbala mi pe: àgabagebe kì yio wá siwaju rẹ̀.
17. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ ẹnu mi ni ifaiyabalẹ, ati asọpe mi li eti nyin.
18. Wò o nisisiyi emi ti ladi ọ̀ran mi silẹ; emi mọ̀ pe a ó da mi lare.
19. Tani on ti yio ba mi ṣàroye? njẹ nisisiyi, emi fẹ pa ẹnu mi mọ, emi o si jọwọ ẹmi mi lọwọ.