1. Wò o, oju mi ti ri gbogbo eyi ri, eti mi si gbọ́ o si ti ye e.
2. Ohun ti ẹnyin mọ̀, emi mọ̀ pẹlu, emi kì iṣe ọmọ-ẹhin nyin.
3. Nitotọ emi o ba Olodumare sọ̀rọ, emi si nfẹ ba Ọlọrun sọ asọye.
4. Ẹnyin ni onihumọ eke, oniṣegun lasan ni gbogbo nyin.
5. O ṣe! ẹ ba kuku pa ẹnu nyin mọ patapata! eyini ni iba si ṣe ọgbọ́n nyin.
6. Ẹ gbọ́ awiye mi nisisiyi, ẹ si fetisilẹ si aroye ẹnu mi.
7. Ẹnyin fẹ sọ isọkusọ fun Ọlọrun? ki ẹ si fi ẹ̀tan sọ̀rọ gbè e?
8. Ẹnyin fẹ ṣojusaju rẹ̀, ẹnyin fẹ igbìjà fun Ọlọrun?
9. O ha dara ti yio fi hudi nyin silẹ, tabi ki ẹnyin tàn a bi ẹnikan ti itan ẹnikeji.
10. Yio ma ba nyin wi nitotọ, bi ẹnyin ba ṣojusaju enia nikọ̀kọ.