Job 11:14-20 Yorùbá Bibeli (YCE)

14. Bi aiṣedede kan ba mbẹ lọwọ rẹ, mu u kuro si ọ̀na jijin rére, máṣe jẹ ki iwàkiwa kó wà ninu agọ rẹ.

15. Nigbana ni iwọ o gbe oju rẹ soke laini abawọn, ani iwọ o duro ṣinṣin, iwọ kì yio si bẹ̀ru.

16. Nitoripe iwọ o gbagbe òṣi rẹ, iwọ o si ranti rẹ̀ bi omi ti o ti ṣàn kọja lọ.

17. Ọjọ aiye rẹ yio si mọlẹ jù ọsan gangan lọ, bi okunkun tilẹ bò ọ mọlẹ nisisiyi, iwọ o dabi owurọ̀.

18. Iwọ o si wà lailewu, nitoripe ireti wà, ani iwọ o rin ilẹ rẹ wò, iwọ o si simi li alafia.

19. Iwọ o si dubulẹ pẹlu kì yio si sí ẹniti yio dẹ̀ruba ọ, ani ọ̀pọ enia yio ma wá oju-rere rẹ.

20. Ṣugbọn oju eniakenia yio mófo, nwọn kì yio le sala, ireti wọn a si dabi ẹniti o jọwọ ẹmi rẹ̀ lọwọ.

Job 11