Job 10:18-21 Yorùbá Bibeli (YCE)

18. Njẹ nitorina iwọ ha ṣe bí mi jade lati inu wá? A! emi iba kúku ti kú, ojukoju kì ba ti ri mi!

19. Emi iba dabi ẹniti kò si ri, a ba ti gbe mi lati inu lọ si isà-okú.

20. Ọjọ mi kò ha kuru bi? dawọ duro, ki o si jọwọ mi jẹ ki emi fi aiya balẹ diẹ.

21. Ki emi ki o to lọ sibi ti emi kì yio pada sẹhin mọ́, ani si ilẹ òkunkun ati ojiji ikú.

Job 10