Job 10:1-5 Yorùbá Bibeli (YCE)

1. AGARA ìwa aiye mi da mi tan, emi o tú aroye mi sode lọdọ mi, emi o ma sọ ninu kikorò ibinujẹ ọkàn mi.

2. Emi o wi fun Ọlọrun pe, o jare! máṣe dá mi lẹbi; fi hàn mi nitori idi ohun ti iwọ fi mba mi jà.

3. O ha tọ́ si ọ ti iwọ iba ma tẹ̀mọlẹ̀, ti iwọ iba fi ma gan iṣẹ ọwọ rẹ, ti iwọ o fi ma tan imọlẹ si ìmọ enia buburu?

4. Oju rẹ iha ṣe oju enia bi? tabi iwọ a ma riran bi enia ti iriran?

5. Ọjọ rẹ ha dabi ọjọ enia, ọdun rẹ ha dabi ọdun enia?

Job 10