21. Nwọn si fi Ṣekemu fun wọn pẹlu àgbegbe rẹ̀, ni ilẹ òke Efraimu, ilu àbo fun apania, ati Geseri pẹlu àgbegbe rẹ̀;
22. Ati Kibsaimu pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-horoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.
23. Ati ninu ẹ̀ya Dani, Elteke pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gibbetoni pẹlu àgbegbe rẹ̀;
24. Aijaloni pẹlu àgbegbe rẹ̀, Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.
25. Ati ninu àbọ ẹ̀ya Manasse, Taanaki pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Gati-rimmoni pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu meji.