Joṣ 13:32-33 Yorùbá Bibeli (YCE)

32. Wọnyi li awọn ilẹ-iní na ti Mose pín ni iní ni pẹtẹlẹ̀ Moabu, li apa keji Jordani, lẹba Jeriko ni ìha ìla-õrùn.

33. Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.

Joṣ 13