41. Joṣua si kọlù wọn lati Kadeṣi-barnea lọ titi dé Gasa, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ani titi dé Gibeoni.
42. Ati gbogbo awọn ọba wọnyi ati ilẹ wọn, ni Joṣua kó ni ìgba kanna, nitoriti OLUWA, Ọlọrun Israeli, jà fun Israeli.
43. Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.