4. Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ.
5. Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.
6. Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa.
7. Bẹ̃ni Joṣua gòke lati Gilgali lọ, on ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, ati gbogbo awọn alagbara akọni.
8. OLUWA si wi fun Joṣua pe, Má ṣe bẹ̀ru wọn: nitoriti mo ti fi wọn lé ọ lọwọ; ki yio sí ọkunrin kan ninu wọn ti yio le duro niwaju rẹ.