28. Li ọjọ́ na ni Joṣua kó Makkeda, o si fi oju idà kọlù u, ati ọba rẹ̀; o pa wọn run patapata, ati gbogbo ọkàn ti mbẹ ninu rẹ̀, kò kù ẹnikan silẹ: o si ṣe si ọba Makkeda gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.
29. Joṣua si kọja lati Makkeda lọ si Libna, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si fi ijà fun Libna:
30. OLUWA si fi i lé Israeli lọwọ pẹlu, ati ọba rẹ̀: o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀; kò kù ẹnikan ninu rẹ̀; o si ṣe si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi o ti ṣe si ọba Jeriko.
31. Joṣua si kọja lati Libna lọ si Lakiṣi, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, o si dótì i, o si fi ìja fun u.
32. OLUWA si fi Lakiṣi lé Israeli lọwọ, o si kó o ni ijọ́ keji, o si fi oju idà kọlù u, ati gbogbo ọkàn ti o wà ninu rẹ̀, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o ṣe si Libna.
33. Nigbana ni Horamu ọba Geseri gòke lati ràn Lakiṣi lọwọ; Joṣua si kọlù u ati awọn enia rẹ̀, tobẹ̃ ti kò fi kù ẹnikan silẹ fun u.
34. Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u;